Take a fresh look at your lifestyle.

Ojú òpó Ayélujára Mẹ́rìn-lé-ní-okòó-din-lẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ́ta ni wọ́n dá silẹ láti da ìjọba láàmú-Lai

Ademọla Adepọju

68

Minisita fún ìròyìn àti àsà lórílẹ̀ èdè Nàíjíríà, Alhaji Lai Mohammed ti ni, 0jú òpó Ayélujára Mẹ́rìn-lé-ní-okòó-din-lẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ́ta ni àwọn ọlọ̀tẹ̀ kan dá silẹ láti da ìjọba láàmú, ni eyi ti wọn n lo láti máa gbé àwọn ìròyìn ẹlẹ́jẹ̀ jáde sójú òpó ayélujára .

lara awọn iroyin ẹlẹje ti wọn gbe sita ni nipa  pe aarẹ Muhammadu Buhari.ni arun ọpọlọ .

“ Eleyi ti o tun ya mi lẹnu ni iroyin ẹlẹjẹ miran to sọ pe aarẹ  Buhari wa ni  UK fun itọju aisan , nitori pe  aarẹ Buhari ko lee da awọn ẹbí rẹ ̀mọ̀ mó, ti wọn si sọ pe, ki o fi ipo aarẹ silẹ”’ .

Mohammed   sọrọ yii niluu Abuja lasiko to n tẹwọgba ajọ to n mojuto eto ibaraẹnisọrọ lorilẹ ede Naijiria niluu Abuja, lọjọ Aje.

Lai tun ni”Iroyin ẹlẹjẹ maa n sakoba fun  isọkan orilẹ ede ni, ki i se ijọba nikan lo n sakoba fun bi ki i se gbogbo ọmọ orilẹ ede Naijiria.

”Opọlọpọ igbeyawo ni awọn ahesọ iroyin yii ti tuka,ti ọpọlọpọ awọn eniyan miran si tun ti sọ ẹ̀mí wọn nu , ti awọn miran si tun ti gba ẹmi ara wọn,nipasẹ awọn ahesọ iroyin wọnyi, paapaa julọ awọn iroyin lati  orí ẹ̀rọ ayelujara” .

Minista tun tẹsiwaju lati sọ iroyin ahesọ miran  nipa isẹ́ ,ni eyi ti awọn eniyan bi i ẹgbẹ́ta kò ba ti padanu ẹmi wọn .

“Ọmọkunrin kan lo fi iwe igbanisisẹ si ́ile-isẹ ologun fun awọn eniyan ẹgbẹ́ta, ni eyi ti o si gba ẹgbẹrun mẹwaa (ten thousand naira) lọwọ ọkọokan wọn.

“O wa ni ki gbogbo wa si ile-isẹ ologun to wa ni Okitipupa ni ipinlẹ  Ondo lọjọ to fun wọn ni iwe igbanisisẹ.

“Bakan naa ni, arakunrin yii tun wa pe adari ikọ ologun ẹkun naa pe ikọ  Boko Haram fẹ wa si bareki naa, lati wa se ọsẹ́ nibẹ’’ .

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.