Take a fresh look at your lifestyle.

Láìsí ètò ààbò kò le sí ìdàgbàsókè, ẹ sọ̀rọ̀ tó le mú ìdàgbàsókè wàá-Lai Muhammed

Ademọla Adepọju

83

Mínisità fún ètò ìròyìn àti àsà lórílẹ̀ èdè Nàíjíríà , Alhaji Lai Mohammed ti ní àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Nàíjíríà  ní àṣẹ lábẹ́ òfin láti  sọ̀rọ̀ tó bá ní sẹ pẹ̀lú ohun tó ń ṣe wọ́n, sùgbọ́n kìí se ọ̀rọ̀ tí ó leè dá wàhálà sílẹ̀ tàbí èyí tí ó le pí́ orílẹ̀ èdè Nàíjíríà ýẹlẹ-yẹ́lẹ, tàbí èyí tí ó leè dá ogun sílẹ̀.

Minisita wa rọ ajọ to n mojuto eto ibaraẹnisepọ (Nigerian Institute of Public Relations ,NIPR)gẹgẹ bi ajọ ti ọrọ orilẹ ede Naijiria ká lara, lati maa bẹnu atẹ lu awọn to n gbero ogun lati tu orilẹ ede Naijiria kàá.

Minisita sọrọ yii niluu Abuja lọjọ Aje , lasiko to n tẹwọgba  aarẹ  ajọ NIPR, ọgbẹni Muktar Sirajo ati awọn ọmọ ẹgbẹ rẹ, siwaju ọjọ ipade gbogbogboo ti wọn yoo se ni ipinlẹ  Bauchi ni ogúnjọ́ , osu karun un ọdun 2021.

Ojúṣe ọkọọkan wa ni lati lo ipo wa lati maa sọrọ to lee mu eto idagbaseko wa si orilẹ ede Naijiria., Inu mi dun pe ile-isẹ NIPR yoo lo ipo wọn lati fọwọsowọpọ pẹlu ijọba lati ri i pe orilẹ ede Naijiria wa ni isọkan pẹlu alaafia.

“Laisi eto aabo ko lee si idagbasoke to mọnyan lori, idi niyi ti ijọba yii ko se ni kaarẹ lati ri i pe alaafia joba ni orilẹ ede Naijiria. Ibi yii ni mo ti lero pe, ẹ lee ti darapọ mọ ijọba lati ran ijọba lọwọ ninu igbiyanju yii. “

Alhaji Lai tun wa rọ ajọ ọhun lati tun lo ipo wọn lati tubọ maa gbogun ti awọn iroyin ẹlẹ́jẹ̀, ki wọn ṣi maa  tun gbogun ti ọmọ egbẹ NIPR ti wọn ko kii tẹle ilana isẹ́ wọn, nitori awọn ìjẹ-kújẹ ti wọn n ri gbà.

Aarẹ ajọ NIPR naa, ọgbẹni Sirajo, naa wa bẹnu atẹ lu awọn oloselu kan ti wọn n lo eto iselu lati da wahla silẹ lori  eto aabo orilẹ ede Naijiria , nitori eto aabo orilẹ ede Naijiria ti ju ti eto iselu lọ.

 

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.