Take a fresh look at your lifestyle.

Iku dóró,olóyè Dogonyaro di olóògbè, ààrẹ Buhari kẹ́dùn lórí ikú rẹ̀

Ademọla Adepọju

142

Ààrẹ Muhammadu Buhari ti sàpéjúwe ikú mínísítà fún ètò ààbò tẹ́lẹ̀rí ajagunfẹ̀yìntì, olóyè Joshua Dogonyaro gẹ́gẹ́ bí  “ipadanu ńlá fún iko ọmọ ogun oriĺẹ̀ èdè Nàíjírià àti ìlú Naijiria lapapọ nitorii ẹmi ìfokànsiǹ àti ìfẹ́ rẹ si ìlú  bàbá rẹ̀.”

aarẹ tun ni gẹgẹ bi ajagunfẹyinti to mo isẹ , ti o si tun jáfafa lẹnu isẹ́ “Ko rọrun lati fi ẹmi ara ẹni lelẹ fun orilẹ ede , nitori eyi lo jẹ  ohun ètùtù to ti eniyan lee se fun orilẹ ede rẹ, eyi si ni oloogbe Dongoyaro se fun ilu Naijiria.”

Aarẹ  Buhari wa ba  ẹbi,ijọba ati gbogbo ọmọ  ipinlẹ  Plateau kẹdunn iku rẹ.O wa gbadura pe ki Ọlọrun tẹ oloogbe naa si afẹrẹ ire.

oloogbe Joshua Dogonyaro jẹ Ọlọrun nípè ni ile-iwosan Faisit ti ilu Jos ni aarọ ỌjọBọ.lẹyin aisan ranpẹ.

A bi oloogbe Dogonyaro lọdun  1940 ni Vom, ni ipinlẹ Plateau . O darapọ mọ ikọ ọmọ ogun orilẹ ede Naijiria lọdun 1964 , ibẹ lo si wa ti o fi di ọkan lara oludari ikọ ọmọ ogun ti ẹkun  keji  Mechanised Division, to wa niluu Ibadan lọdun 1987.

o jẹ ọga ọmọ ogun orilẹ ede  Naijiria ni odun  1988 , o si fẹyiti ninu isẹ ologun lọdun 1993.

Leave A Reply

Your email address will not be published.