Take a fresh look at your lifestyle.

Eid-Al-Fitr: Ààrẹ Buhari gbàdúrà nílé ààrẹ nílùú Àbújá

Ademọla Adepọju

278

Ààrẹ Muhammadu Buhari náà darapọ̀ mó àwọn akẹ́gbẹ́ rẹ̀ lórílẹ̀ èdè àgbáyé  ní Ọjọ́Bọ̀ láti gbàdúrà lọ́jọ́ ayẹyẹ Eid-al-Fitr pẹ̀lú àwọn ẹbí àti òsìsẹ́ rẹ̀ nílé ààrẹ tó wà nílùú Àbújá.

Adura naa ni won se lati fi kẹyin  ayẹyẹ itunu àwẹ̀.

Oluranlọwọ aarẹ lori iroyin ati ikede , Garba Shehu  ti sọrọ ninu atẹjade kan ti o gbe jade lọsẹ to kọja pe aarẹ Buhari yoo maa gbadura lasiko itunu awẹ nile aarẹ to wa niluu Abuja, pẹlu ilana ti o rọ mọ Covid-19 , ni eyi ti igbimọ to n sakoso gbigbokun ti ajakalẹ aarun aarun Korona ti aarẹ yan.

Aarẹ tun sàdúrà pẹlu  abẹnugan ile igbimọ asofin, Ahmed Lawan, agẹnugan ile igbimọ asoju , Femi Gbajabiamila, oluranlọwọ aarẹ fun eto aabo , Babagana Monguno,adari osiẹ aarẹ , ọjọgbọn Ibrahim Gambari.

A tun ri aarẹ ti o tun sadura pẹlu iyawo ati awọn ọmọ rẹ.

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.