Take a fresh look at your lifestyle.

Ọbasa ki awọn musulumi ku ọdun Itunu Aawẹ, o pe fun ẹmi iṣọkan ati ifọkanjin

110

Agbenuso Ile Igbimo Asofin Ipinle Eko, Asofin Mudashiru Obasa pe fun emi isokan laarin awon omo orile-ede Naijiria, eleyii ti yoo mu won bori awon ipenija ti orile-ede yii n koju bayii.

Agbenuso Obasa soro yii ninu oro ikini ku odun re fun awon musulumi ninu ayeye odun Itunu Aawe odun 2021 yii. Agbenuso naa wa ro Aare Mohamadu Buhari ti orile-ede Naijiria lati lati gbe igbese lori awon ohun ti igbimo awon gomina lapa Gusu orile-ede yii n beere fun.

Asofin Obasa fi igbagbo han pe awon ipenija oro-aje ati ti aabo ti orile-ede yii n koju bayii yoo le je ki o lagbara si i nigba ti o ba kuro ninu won. Ati pe o se pataki ki aare tele imoran igbimo awon gomina apa Gusu orile-ede yii.

Agbenuso Ile naa, ti o je Alaga ana fun igbimo awon agbenuso Ile Igbimo Asofin Ipinle orile-ede Naijiria so pe “Bi Aare Buhari ba se n gbe awon ibeere gomina yii ye wo, ni ki o sise le e lori loju ese fun ilosiwaju orile-ede yii”

Ninu oro re fun awon ara ilu, o ni: “anfani nla ni Aawe Ramadan je fun wa lati fi gbadura fun orile-ede wa, nitori laisi aniani orile-ede yii n koju awon ipenija kan.”

“Ewe, a ko le fi awon ipenija yii da ijoba nikan soso. Omo orile-ede yii kookan lo ni ipa lati ko, lati mu igberu ba orile-ede yii. A je olusin Olorun pupo ni orile-ede yii. Ohun ti esin si n ko wa ni pe ka ni ife ara wa lokunrin ati lobinrin, ki a si bara wa gbe lalaafia.”

Agbenuso naa tun ki gbogbo musulumi ku oriire fun opin aawe Ramadan to soju emi won. O ni:

“Leyin ajoyo yii, e je ka maa bara wa fife lo, ki a si maa tele ofin Olorun Allah, ki a si ri i daju pe alaafia joba, ki a si maa gbadura fun ilosiwaju orile-ede yii.”

Leave A Reply

Your email address will not be published.