Aáwọ̀ okòwò: Ààrẹ Bùhárí rán Àwọn Aṣójú Sí orílẹ̀-èdè Ghánà
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Mùhámmádù Bùhárí ti ṣọ pé kí aṣojú kán lọ sí orílẹ̀-èdè Ghánà láti yanjú aáwọ̀ ọlọ́jọ́ pípẹ́ tó ti wà láàrin àwọn oníṣòwò Nàìjíríà àti ìjọba orílẹ̀-èdè Ghánà.
Eyi jẹyọ ninu atẹjade kan ti oluranlọwọ pataki fun iroyin si Minisita ile- Iṣẹ, okowo ati Idokoowo, Ifedayo Sayo bọwọ lu.
Minisita fun ile-iṣẹ,okowo ati idokoowo,Ọgbẹni Adeniyi Adebayọ, ni o dari ikọ naa pẹlu awọn to tun ṣe pataki.
Wọn yoo tubọ fọrọjomitoro ọrọ pẹlu awọn alaṣẹ orilẹ-ede Ghana pẹlu ipinnu lati wa ojutuu si aawọ ọhun.
Minisita naa sọ pe ,aṣoju ikọ naa yẹ ki o ṣe abẹwo naa laarin ọjọ kọkanle-lọgbọn oṣu karun ati ọjọ kinni oṣu kẹfa,ọdun 2021.
Leave a Reply