Take a fresh look at your lifestyle.

Ẹ̀yin agbódegbà àti fàyàwọ́,ẹ tọwọ́ ọmọ yín bọsọ, kẹ́ máa jẹyán yín níṣu-Adamu

Ademọla Adepọju

166

Ilé isẹ́ asọ́bodè orílẹ̀ èdè Nàíjíríà ti ẹkùn Ọyọ/Ọsun ti kéde  pé òhun ti pa owó tó lé díẹ̀ ni Bilioni Márùndínlógún (N15,890,479.26) ní àlàfo ọjọ́ kínni osù kejì sí ọgbọ̀njọ́ osù kerin ọdún tí a wà nínú rẹ, pẹ̀lú àwọn àseyọrí ọlọkan-ò-jọ̀kan míran.

Oludari  asọbode ni ẹkun Ọyọ/Ọsun, Comptroller Adamu Abdulkadir lo sọ ọrọ yii lasiko ti Ile isẹ ọhun n se afihan awọn ẹru fayawọ(contraband), ninu eyi ti wọn ti ri ẹru bii irẹsi  Ilẹ okeere; ororo ìsebẹ̀; epo  rọbi (petrol); ẹja gbigbẹ; Igbo(canabis sativa); aloku asọ ati bata; pẹlu ọkọ ayọkẹlẹ DAF.

Afihan wọnyi lo waye ni ẹkun Ọyọ/Ọsun Ile isẹ asọbode Naijiria ti o kalẹ si agbegbe Ikọlaba niluu Ibadan ti i se olu ilu ipinlẹ Ọyọ, ti o wa ni ẹkun gusu iwọ oorun orilẹ ede Naijiria.

Nigbati o n salaye aseyọri ẹkun Ile isẹ ọhun,  Adamu gbe osuba kare fun awọn osisẹ rẹ pe awọn ni igi lẹyin ọgba aseyọri ti ẹkun Ile iẹe naa ri tọka si.

Bakan naa, ni Adamu dupẹ lọwọ awọn asaju ati ọba ilu ati gbogbo awọn ti ọrọ naa kan laiyọ gbogbo ọmọ bibi ati olugbe ẹkun Ọyọ/Ọsun silẹ fun ifọwọsowọpọ wọn to mu ki aseyọri wọnyi se e se.

Adamu wa fi asiko naa kilọ fun gbogbo awọn eniyan to n se agbodegba fun awọn onifayawọ ti wọn n doju ija kọ awọn osisẹ Ile isẹ asọbode pe ki wọn lọ tọwọ ọmọ wọn bọ asọ ki wọn maa ba jẹ iyan wọn nisu.

Ọga agba  ti ẹkun Ile isẹ naa n rọ gbogbo onisowo ẹkun Ọyọ/Ọsun  lati se okoowo wọn lọna ẹtọ, o tẹnumọ ọrọ oga agba Ile isẹ asọbode orilẹ ede Naijiria, , ajagunfẹyinti Ibrahim Ali (Rtd) ẹni ti o fi idi rẹ mulẹ pe ẹnu’bode Ọyọ ati Ọsun si wa ni titi pa, ninu eyi ti ko gbọdọ si kara- kata kankan ni awọn ẹnu iloro wọnyi titi di asiko ti ijọba orilẹ ede Naijiria yoo si ẹnu’bode wọnyi silẹ.

 

 

Abiọla Ọlọwẹ

Leave A Reply

Your email address will not be published.