Take a fresh look at your lifestyle.

Ẹ kú ogun àjàbọ́, sé ewu iná kìí pàwòdì-Aarẹ Buhari kí àwọn ọmọ ilé-ẹ̀kọ́ Afaka,ìpínlẹ̀ Kaduna

0 364

Asalẹ Ọjoru yii ni aarẹ Muhammadu Buhari tẹwọgba awọn ọmọ ile-ẹkọ mẹtadinlọgbọn to  wa ni ile ẹkọ giga to n kẹkọọ nipa  igbo igbalode,, eyi to wa ni Afaka, ni  ipinlẹ Kaduna ti awọn ajinigbe ko sinu ahamọ wọn .

Aarẹ  Buhari wa ba awọn ẹbi ,ọrẹ  ati ipinlẹ Kaduna yọ fun ogun ajabọ, ti ko pa awado wọn soju ogun.

Ninu atẹjade kan ti ile -isẹ aarẹ  gbe jade pe :

“Inu wa dun bi awọn ọmọ ile -ẹkọ  naa ṣe gba itusilẹ .A dupẹ gidi- gidi lọwọ awọn ti wọn ran wa lọwọ, paapaa julọ ile-ise eto aabo, ajọ to n mojuto eto ayika ati ijoba ipinlẹ Kaduna.A si tun dupẹ pupọ lọwọ gbogbo ọmọ orilẹ ede Naijiria fun adura wọn.” 

Aarẹ Buhari wa rọ gbogbo ọmọ orilẹ ede Naijiria lati fọwọsowọpọ pẹlu awọn ile-isẹ to n mojuto eto aabo ki eto aabo lee tubọ fẹsẹ mulẹ sii lorilẹ ede Naijiria.

Aarẹ tun wa  bẹbẹ fun itusilẹ gbogbo awọn ọmọ orilẹ ede Naijria to wa ni ihamọ awọn ajinigbe  , paapaa julọ awọn ọmọ ile-ẹkọ Fasiti ti Greenfield..

 

Ademọla Adepọju

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button