Take a fresh look at your lifestyle.

Ìpàdé Ààbò orílẹ̀-èdè Tẹ̀síwájú

42

Ààrẹ Mùhámmádù Bùhárí ń tẹ̀síwájú pẹ̀lú Ìpàdé Ààbò ní Víllà, Àbújá.
Ipade naa ti aarẹ orilẹ-ede Naijiria pe ni ọjọ Jimọh to kọja, ti sun siwaju titi di oni (Ọjọbọ).
O n waye ni yara Apejọ ti Iyaafin akọkọ, nitori pe wọn nṣe atunṣe gbangan awọn igbimọ ti wọn ti nṣe iru ipade bẹẹ lọwọ.
Awọn ti o wa nijoko nibi ipade naa ni igbakeji aarẹ orilẹ-ede, Yẹmi Osinbajo,akọwe agba fun orilẹ-ede,ọgagun Mustapha ati ọga agba fun awọn oṣiṣẹ aarẹ,ọmọwe Ibrahim Gambari.
Awọn to tun kopa ninu ipade naa nii minisita fun aabo,ajagun fẹyinti Bashir Magashi ati onimọran aabo orilẹ-ede,ajagunfẹyinti Babagana Monguno.
Olori Aabo, ọgagun Lucky Irabor, Oloye agba fun awọn Oṣiṣẹ Ologun; Lieutenant-General Ibrahim Attahiru, Oloye agba fun awọn Oṣiṣẹ oju omi; vice Admiral Awwal Zubairu, ati ọga agba fun awọn oṣiṣẹ oju ọrun , Air Marshal Isiaka Amoo tun wa nibi ipade pataki naa.
Ọga agba fun awọn ọlọpa, Usman Baba naa wa nibẹ.

Ijinigbe ati ipaniyan ti o ngbegele lẹnu ọjọ mẹta yii ni awọn agbegbe kan ni o fa ipade aabo yii.
Eyitayọ Fauziat Oyetunji

Leave A Reply

Your email address will not be published.