Take a fresh look at your lifestyle.

Ẹ̀sùn ìbàjẹ́: Àwọn agbátẹrù Grammy yí òfin padà

Ademọla Adepọju

43

Àwọn agbátẹrù ife ẹ̀yẹ Grammy ti kéde lọ́jọ́ Ẹti láti fòpin sí ohun tí wọ́n ń pè ní ìgbìmọ̀  “Ìkọ̀kọ̀”, ní èyí tí àwọn ènìyàn ti ń fi ẹ̀sùn kàn pé wọn ń se ojú-sàájú sí bí wọn se ń fún àwọn kan ní ife ẹ̀yẹ nípa orin kíkọ.

Awọn ile -isẹ eto orin kikọ ọhun sọ pe eto idibo awọn ẹ̀ẹ́dẹ́gbàfà ni  awọn  yoo maa  fi yan  ẹni to ba maa gbégbá orókè fun ife ẹyẹ ti yoo waye ni osu kinni, ọdun  2022, ki i se nipa ọmọ ẹgbẹ ti iye wọn to marundinlogun tabi ọgbọ̀n mọ ọn.

lọdun to kọja ni awọn kan fi ẹ̀sùn kan ile-isẹ naa bi  akọrin ọmọ orilẹ ede Canada,Weeknd ko se rí ẹnikankan dibo fun un, bo tilẹ jẹ pe àwon orin ti o ṣe, ni eyi ti o pe ni “Lẹyin awọn Wakati” ni o gba ayé kan lasiko to jade sita lọdun 2020.

 Weeknd,tun wa kọ ọ si ori ẹrọ Twitter rẹ losu kọkanla , ọdun to kọja pe “Iwa ibajẹ ti wa ni  ile-isẹ Grammy , nitori naa wọ́n gbọdọ tọrọ aforiji  lọwọ awọn olufẹ rẹ ati oun naa.”

Lọdun 2019 ni oludari ile-isẹ to n maa n gbe àwo sita,Deborah Dugan ni o ti kọkọ fi ẹsun kan ile-isẹ Grammy  nile ẹjọ́, lori ọna ti wọn fi maa n yan awọn to ba gbegba oroke fun ife ẹyẹ.

Bo tilẹ pe   ile -isẹ Grammy da ọrọ naa nu pe, ahesọ ati  pe irọ patapata to jinna si ootọ ni ẹsun  ti Deborah Dugan  fi kan wọn.

Bakan naa, akọrin ilu mọ̀-ọ́n-ká ọmọ orilẹ ede America,Halsey naa ti fi ẹsun kan ile-isẹ Grammy lọfun to kọja  nipa bi wọn se n yan awọn oludije fun ife ẹyẹ ọhun.O wa rọ wọn lati maa yan awọn oludije wọn lọna ti ko ni fi mu oju saaju lọwọ.

Leave A Reply

Your email address will not be published.