Take a fresh look at your lifestyle.

Ẹ̀yin akọròyìn, ẹ máa fi òmìnira ìròyìn yín da omi àlàáfíà ìlú rú -Aarẹ Buhari

Ademọla Adepọju

43

Ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàíjíríà, Muhammadu Buhari ti rọ àwọn akọ̀ròyìn láti máa se lo òmìnira tí wọ́n ní, fi da omi  àlàáfíà ìlú rú tàbí fi dá  àríyànjihàn sílẹ̀ ní orílẹ̀ èdè. Ààrẹ tún wá rọ àwọn akọ̀ròyìn láti yàgò fún  ọ̀rọ̀ ìkórira àti èyí tó leè dá wàhálà silẹ ni orilẹ ede .

Aarẹ  Buhari sọrọ yii lati fi sami ayẹyẹ ojọ ominira awọn akọroyin lagbaaye, ni eyi to maa n waye ni ọjọ kẹta , osu karun un, aarẹ tun tẹnumọ pe oun ko ni kaarẹ lati tubọ ri i pe awọn akọroyin jẹgbadun ominira nipa kikọ iroyin wọn.

Aarẹ Buhari tun tẹsiwaju pe ominira fun awọn akọroyin tun wa lara awọn nnkan to lee mu ki idagbasoke ba  eto ijoba tiwa-n-tiwa lorilẹ ede. O wa rọ awọn akọroyin lati lo anfaani naa, lọna to tọ́ ati to yẹ.

Aarẹ Buhari tun wa seleri lati maa tubọ fọwọsowọpọ pẹlu awọn akọroyin lojuna ati maa se isẹ wọn, ni ibamu pẹlu  akori ti  ajọdun ọdun yii , ‘Lilo iroyin lati mu idagbasoke ba Awujọ.’

O wa rọ akọroyin ile -isẹ ijọba lati maa lo gbogbo nnkan to wa ni ikawọ wọn fun idagbasoke awujọ,ki awọn akọroyin ṣi maa lo ominira ti wọn ni lati kọ iroyin wọn lọna ti yoo fi rọrun.

 

.

Leave A Reply

Your email address will not be published.