Take a fresh look at your lifestyle.

A ò ní sòfin tí yóò tako òmìnira àwọn akọròyìn- Ahmad Lawan

Ademọla Adepọju

69

Abẹnugan ilé ìgbìmọ̀ asòfin lórílẹ̀ èdè Nàíjíríà, Ahmad Lawan, ti ní ile ilé ìgbìmọ̀ asojú asòfin kò ní gbé àbádòfin tàbí òfin tí yóò tako ìlànà òmìnira àwọn akọròyìn orílẹ̀ èdè yìí.

Ahmad sọrọ yii ninu atẹjade kan ti oluranlọwọ rẹ lori iroyin ,Ola Awoniyi gbe jade lati fi ṣe ayajọ ọjọ ominira awọn akọroyin lagbaaye .Abẹnugan  Ahman  sọ pe inu oun dun fun isẹ takun-takun ti awọn akọroyin orilẹ ede yii n se.

Ahmd, wa rọ awọn akọroyin lati yọ awọn èèpò to n ba alikama jẹ ( awọn eniyan buburu) ninu wọn bii jiga.

Lawan, tun wa rọ awọn akọroyin lati máa se kuna ninu ojuse wọn lati  maa se itọpinpin gẹgẹ bi ajafitafita ti awujọ ati  ipele kẹrin nibi isejọba ti wọn wa .

“ Mo gboriyin fun awọn akọni akọroyin ti wọn fi ẹ̀mí wọn lelẹ lojuna isẹ́ wọn, mo gbadura pe wahala wọn ko ni ja si asán. 

“Mo tun rọ awọn adari ẹgbẹ akọroyin lati mojuto awọn iroyin ẹlẹ́jẹ̀ ti awọn ọbayejẹ kan maa n gbe kaakiri.

 

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.