Take a fresh look at your lifestyle.

Ìdùnnú subú layọ̀, aarẹ Buhari fọwọ́sí ẹ̀kúnwó fún awọ̀n òsìsẹ́ fẹ̀yìntì

Ademọla Adepọju

61

Ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàíjíríà, Muhammadu Buhari ti fọwọ́sí ẹ̀kúnwó owó osù fún àwọn òsìsẹ́ fẹ̀yìntì  lórílẹ̀ èdè Nàíjíríà

Aarẹ Buhari se eleyi ni ilana  eto ẹkunwo ti o se fun awọn osisẹ ijọba lọdun 2019.

Akọwe agba fun ilana eto atunse fun osisẹ fẹyinti ,ọmọwe Chioma Ejikeme,lo sọrọ yii pẹlu awọn akọroyin niluu Abuja.

Ejikeme, ni awọn yoo  bẹrẹ ṣi maa san ẹkunwo yii fun awọn osisẹ fẹyinti  lati osu karunun , ọdun 2021 , bẹẹ si ni awọn yoo tun san gbogbo  owo ti wọn jẹ wọn sẹyin lati igba ti ijọba apapọ ti bẹrẹ si maa san ẹkunwo ọhun.

“A o bẹrẹ si ni maa san ẹkunwo awọn osisẹ fẹyinti lati osu kẹrin ọdun 2019 pẹlu eyi ti wọn n gba ni osoosu lati osu karun un ọdun 2021 ” .

O tẹsiwaju pe; “Mo tẹnumọ ọn pe ẹgbẹ osisẹ fẹyinti ko nilo lati maa fẹhonuhan nitori pe , a ti pari gbogbo eto lati maa san  gbogbo owó ifẹyinti wọn.

Ọmọwe Ejikeme  tun wa rọ awọn osisẹ fẹyinti lati maa se fun ẹnikankan ni owo gba maa binu , ki wọn to gba owo wọn, nitori pe ẹ̀tọ́ wọn ni.

Akọwe agba naa tun wa gba awọn osisẹ fẹyinti nimọran lati maa se fun ẹnikankan ni nọmba ti wọn fi n gba owo ni ile ifowopamọ, ki wọn si fi to etí agbofinro, ti ẹnikankan ba fẹ lu wọn ni jibiti.

“A ti pari eto lati bẹrẹ si maa fi atẹjisẹ ransẹ si gbogbo awọn osisẹ fẹyinti , nipa bi a o ṣe maa san owo wọn, ki a si tun kilọ fun wọn lati sọra fun awọn onijibiti.

“Akoko ti to fun awọn osisẹ fẹyinti lati bẹrẹ si maa jẹ èrè isẹ́ ọwọ́ wọn.” 

 

Ademọla Adepọju

Leave A Reply

Your email address will not be published.