Take a fresh look at your lifestyle.

Ẹ jẹ́ àwòkọ́se láti fún àwọn òsìsẹ́ ilé- ẹjọ́ àti asòfin ní òmìnira ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́-alága ẹgbẹ onísòwò ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́

Abiola Olowe

91

Alága ẹgbẹ́ àwọn òsìsẹ́ onísòwò ní  ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ (TUC), Comrade Emmanuel Ogundiran ti rawọ́ ẹ̀bẹ̀ si gomina ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Seyi Makinde láti gbé ìgbésẹ̀ nípa síse àmúlò òmìnira àwọn  òsìsẹ́  asòfin àti ilé-ẹjọ́. Kí ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ leè se àfihàn gẹ́gẹ́ bí asíwájú nínú ohun gbogbo.

Ogundiran tun fi asiko naa rọ gomina lati sa ipa rẹ lati ri  i pe ijinigbe ati isekupani eleyii to n fi ojoojumọ gberu , di afisẹyin ti eegun n fi’sọ. O tun wa rọ awọn osisẹ lati tẹsiwaju ninu iwa  omoluwabi sise, ki ọon maa si fa ẹeyin ninu ipinnu wọn lati ri pe ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ati oril e ede Naijiria dara si.

 

Se eegun nla nigbẹyin igbalẹ,alaga agbarijọ osisẹ (NLC), ẹka tiìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Comrade Kayode Martins wa ke si gbogbo osisẹ jake jadoìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lati fọwọsowọpọ pẹlu isejọba Seyi Makinde  lati koju ipenija eleyi ti ajakalẹ aarun korona ( Covid-19) da silẹ, ki wọn baa le dena irufẹ ipenija bẹẹ lọjọ iwaju.

Comrade Kayode Martins sọrọ yi nibi ajọyo ayajọ ọjọ osisẹ lagbaaye eleyii ti wọn pe akori rẹ ni ”   Ajakalẹ aarun: Ipenija lori eto ọrọ aje  awujọ, eto aabo, isẹ, ati igbaye-gbadun ara ilu”

Alaga ẹgbẹ osisẹ tun salaye ninu ọrọ rẹ pe,  ajakalẹ aarun korona ti se aseyọri nipa sise atunyẹwo igbe aye ẹ̀dá ni awọn ọna bii, eto oselu, ọrọ aje, igbayegbadun, eleiyi ti o faa ti awọn eniyan fi n wa ọna lati koju irufẹ isẹlẹ bẹẹ lọjo iwaju.

 

 

Ademọla Adepọju

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.