Take a fresh look at your lifestyle.

Ẹ gbájúmọ́ ètò ààbò ẹ̀mí àti dúkìá ará ìlú- Seyi Makinde

Ademọla Adepọju

60

Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ Seyi Makinde ti rọ ikọ elétò ààbò ni ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ láti túbọ  jẹ́ kí ìbásepọ̀ tó gbóúnjẹ fẹ́gbẹ́ -gbàwobọ̀  tó dán mọ́rán wà láàrin  ìjọba  àti ikọ̀ eléto ààbò, ki ètò ààbò tó péye  leè wà fún ẹ̀mí àti dúkìá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Gomina Seyi Makinde lo sọrọ yii pẹlu awọn osisẹ jake jado ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lasiko  ayajọ ayẹyẹ ẹgbẹ  awọn osisẹ lagbaye to waye ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ .

Ayẹyẹ ohun lo waye ni Papa isere Ọbafemi Awolọwọ to kalẹ si agbegbe Oke Ado ni Ibadan ti se olu ilu ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ni ẹkun gusu iwọ oorun orilẹ ede Naijiria.

O wa fi kun ọrọ rẹ pe, oun ni igbagbọ ninu awọn osisẹ eleto aabo wi pe wọn ko ni fi igba kan bọkan ninu lati ri daju pe awon omo bibi ati olugbe ipinle naa sun lai ni ifoya.

Gomina tun fi asiko naa lu awọn osisẹ lọgọ ẹnu fun isẹ takuntakun ti wọn n se, eleyii to mu ki ọrọ aje ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ dagbasoke si i. O wa rọ wọn ki wọn tẹsiwaju ninu isẹ rere ti wọn n se.

 

 

 

Abiọla Ọlọwẹ

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.