Take a fresh look at your lifestyle.

Àwọn ọmọ Nàíjíríà tó ń gbé nílẹ̀ òkèèrè ko ni pẹ maa dibo lati ilu ti wọn wa

Ademọla Adepọju

103

Ìgbìmọ̀ ìjọba àpapọ̀ ti fọwọ́sí ètò ìlànà ti yóó  mú ìdàgbàsókè bá àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Nàíjíríà tó ń gbé nílẹ̀ òkèèrè.

Minisita fun ọrọ ilẹ okeere , Geoffrey Onyeama lo sọ eleyii fun awọn akọroyin ile aarẹ lẹyin ipade ti wọn se pẹlu aarẹ  Muhammadu Buhari.

o tẹsiwaju pe eto ilana yii wa fun awọn ọmọ orilẹ ede Naijiria to n gbe nilẹ okeere.

Onyeama tun ni : “Eto ilana yii yoo jẹ ki ibasepọ to mọnya lori  wa laarin ijọba ati awọn ọmọ orilẹ ede Naijiria to n gbe nilẹ okeere, bo tilẹ jẹ pe o le ni miliọnu mẹtadinlogun ọmọ orilẹ ede Naijiria to n gbe nilẹ okeere, ni eyi ti wọn n  ko ipa pataki ni okeere ti wọn wa.

Minisita tun sọ pe eto ilana yii yoo wulo lati lee jẹ ki awọn ọmọ orilẹ ede Naijiria to n gbe nilẹ okeere ni anfaani lati lee dibo lọjọ iwaju , bakan naa ni yoo tun ran wọn lọwọ lati lee lo imọ ti wọn ni nipa eto  ilera ati awọn eto idagbasoke miran fun ilọsiwaju orilẹ ede Naijria.

 

 

 

Ademọla Adepọju

Leave A Reply

Your email address will not be published.