Take a fresh look at your lifestyle.

Lẹ́yìn ọdún mọ́kàndílógún ,pápá eré ìdárayá,National Stadium,yóò gba ìsọdọ̀tun ni osù kẹjọ- Minisita

Ademọla Adepọju

113

Mínísítà fún ìdàgbàsókè  ọ̀rọ̀ àwọn ọ̀dọ́ àti eré ìdárayá lórílẹ̀ èdè  Nàíjíríà, Sunday Dare, ti ní pápá eré ìdárayá , National Stadium,Surulere tó wà ní ìpínlẹ̀ Eko, yóò gba ìsọdọ̀tun , tí wọn yóò ṣí bẹ̀rẹ̀ ṣí máa lòó láti osù Keje lọ, lẹ́yìn ọdún mọ́kàndínlógún tí wọ́n ti pa pápá eré ìdárayá náà tì sẹgbẹ kan.

Minisita sọrọ yii lasiko to n se abẹwo si gomina ipinlẹ Ogun , Dapo Abiodun,ni Abeokuta. Dare  sọ pe atunse ti wọn ṣe si papa ere idaraya naa wa lara ipinnu ajọ rẹ .

Dare, tẹsiwaju pe lati ọdun 1973 ni wọn  ti kọ́  papa ere idaraya ,National Stadium to wa ni  ipinlẹ Eko , sugbọn ti o wa ni  ipo ti ko bojumu nitori pe wọn ko mojuto, bẹẹ si ni ko si atunse kankan lori rẹ lati bi ogun ọdun.

Dare ni papa ere idaraya to wa ni ilu Abuja lee ba akẹgbẹ rẹ kopa lagbaaye , nipa isẹ ribi-ribi ti ajọ rẹ ti se lori rẹ.

nigba ti gomina ipinlẹ Ogun, Abiodun naa n fesi si ọrọ minisita pe,idagbasoke awọn ọdọ  ati ipese isẹ lọpọ janturu wa lara ipinnu marun un ti ijọba rẹ yoo mu lọkunkundun ati lati lee jẹ ki awọn ọdọ lo imọ ti wọn ni  nipa imọ ẹ̀rọ fun idagbasoke ipinlẹ naa yato si iwa yahoo-yahoo.

Ademọla  Adepju

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.