Take a fresh look at your lifestyle.

Igbákejì ààrẹ, Osinbajo yóò sojú Nàíjíríà níbi ayẹyẹ àjọ̀dún òmìnira Ọgọ́ta ọdún orilẹ ede Sierra Leone

Ademọla Adepju

39

Igbákejì ààrẹ, orílẹ èdè Naijiria , Ọjọgbọn Yẹmi Osinbajo  ni yóò máa sojú orílẹ̀ èdè Nàíjíríà níbi ayẹyẹ àjọ̀dún  Ọgọ́ta ọdún (60 years)  ti orílẹ èdè Sierra Leone gba òmìnira, ní èyí tí yóò wáyé ni olú-ìlú orílẹ èdè náà , Freetown ,ní ỌjỌRu.

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ  fun igbakeji aarẹ , Laolu Akande sọ pe, ọjọgbọn  Osinbajo  ni yoo maa darapọ mọ  awọn aarẹ ati asoju orilẹ ede miran ati  lati ilẹ Afirika fun ayẹyẹ naa.

Laolu sọ pe“ Orilẹ ede Naijiria ati Sierra Leone ti jọ ni iriri kan naa nipa ibasepọ  ti win jọ ni lati igba ti wọn wa lọdọ awọn amunisin,”.

o tun tẹsiwaju pe  “lati ọdun ti o ti pẹ ni orilẹ ede mejeeji naa ti ni ibasepọ to dan mọnran lori eto ọrọ aje, idokoowo,  ati eto aabo.”

Akande tun sọ pe minista  ipinlẹ fun eto ọrọ̀ ilẹ okeere, Zubairu Dada,yoo wa lara awọn ti yoo maa tẹle aare lọ fun irinajo ọhun.

Osinbajo  yoo ṣi maa pada de si ilu Abuja lonii baka naa.

 

Ademọla Adepọju

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.