Take a fresh look at your lifestyle.

Ẹ máa jẹ́ kí Àsà àti Ìse Yorùbá wọlẹ̀ :ADACI

Laide Gold

187
  • Ètò ìgbédìde àsà Ilẹ̀ Yorùbá tó wáyé ni gbọ̀ngan Cultural Center Kuto, Abẹokuta ní ìpínlẹ̀ Ogun, abala kan nínú àjọ agbásàga kan lókè òkun ìyẹn African Diaspora Ancestral Commemoration Institute tó wà ní ìlú Washington DC lórílẹ̀ èdè Amerika ló gbé ètò gbangba l’Àsá-ń-ta náà kalẹ̀ fún àwọn akẹkọọ ní ìpínlẹ̀ Ogun gẹ́gẹ́ bii móríyá àti ìdánrawò ìkájú òsùwọ̀n nínú àsà.

Idije ara ọtọ naa ti wọn pe ni ‘GBÀGEDE ÀSÀ’ ni wọn gbe kalẹ fawọn ọmọ ile ẹkọ girama lati kopa ojukoju ninu àwọn nnkan tawọn olukọ ti kọ wọn gege bi alakalẹ atẹ ikawe ti ijoba ipinle Ogun fọwọsi. Ninu ọro ti Aarẹ ajọ naa, oloye Fakunle Oyesanya sọ, lo ti salaye pe, erongba ADACI NIGERIA ni lati mu ọkàn àwọn ọ̀dọ́ pada wa sinu asa ati ise Ilẹ̀ Yorùbá paapaa julo lati maa fi ede Yoruba yangan nibi gbogbo ti wọn ba lọ. Fakunle tesiwaju ninu alaye rẹ pe, ohun to dara ni lati la ọ̀nà ti àwọn ọ̀dọ́ yoo tọ̀ fun wọn nipase asa ati pe wọn gbọdọ le sọ ede abinibi to dantọ kiwọn si mo nipa orisun wọn. “O se pataki lati je ki oju àwọn ọ̀dọ́  là sí asa ati ise ile adulawọ, ki awa obi ati alagbatọ jẹ ki awọn ọ̀dọ́  mọ̀ pe asa ati ise ẹni, ni isura pataki,to le jẹ ki wọn ba àwọn eniyan pataki pe lawujo.

Bakan naa ni o se pataki fun wọn lati mọ pe awọn ni ọjọ́ ọ̀la ti yoo gbe asa ilẹ̀ adulawọ ga. Ile-isẹ ijọba to n mojuto asa ati ise ni ipinlẹ naa lo siju idije naa ni aago mọkanla owurọ pelu ifọwọsi ile isẹ́ ijọba to n mojuto ilana eto ẹ̀kọ́.

Awọn akẹkọọ to dantọ ni ile iwe girama kọọkan fi ransẹ lati dije lorukọ ileewe wọn, nigbati afibo ijo,ilu,ewi, ẹkun iyawo ati oriki orile lorisiirisii n wole laarin idije ọhun gẹgẹ bi itura ati idaraya, eyi naa waye lati fidi asa ati ise Yorùbah mulẹ̀.

Awọn oloruko lawujo niwọn peju-pesẹ sibi idije asa naa tiwọn bawọn fi oju lameyitọ wo awọn akẹkọọ  tiwọn pegede lara wọn ni, gbajugbaja sorosoro lori redio ,Oloye Bunmi Ayelaagbe, afedesewa Ayo Ewebiyi mama oriki, atawọn akewi bii Abel Ojetunde,Baakini, omooba Olaitan Oladele aare egbe apede Yoruba ati sọrọsọrọ lori redio Adebisi Aderinto. Ninu esi asekagba idije naa ni ile-iwe Reverend Kuti Memorial Grammar school ti jawe olubori nigbati Baptist Boys High School di ipo keji mu nibi ti Baptist Girls High School ti se ipo kẹta. Ẹbun owo to kaju owo idanwo asekagba ileewe girama iyen WAEC ọdun 2021 ni wọn fun akẹkọọ  kookan to jawe olubori, bakan naa ni ẹbun gba ma binu wa fawọn akẹkọọ  tiwọn gbiyanju.

Oloye Okemuyiwa Gbolahan ninu oro tirẹ, nigba to n fun àwọn akẹkọọ  naa lẹbun ati iwe eri akopa lórúkọ ADACI NIGERIA lo ti salaye pe, ki awọn akẹkọọ  naa tesiwaju lati mu asa ati ise Yoruba ni pataki toripe iru idije bayi tun le waye lojo miran ti yoo fẹju ju eleyi lọ.

Ẹwẹ, abileko Laide Gold toun naa jẹ okan pataki ninu ajọ naa, nigbati o n fun àwọn oluko lẹbun loruko ajo naa sọ pe, awọn oluko gan an alara lo yẹ ki wọn gba osuba Kare nitoripe awọn ni wọn ko awọn akẹkọọ  naa lawọn nnkan to yẹ ki wọn mọ, lati fakọyọ ninu idije naa o ni, ” Bi dokita alabẹrẹ ba pa eeyan meji pere, ko soro lati mọ toripe awọn eeyan yoo fi sapejuwe gẹgẹ bi apaayan sugbọn oluko le pani lai mu ọfà lọwọ, nnkan ti oluko ba kọni nii wa lagbari ẹni nitori naa, ohun to yẹ ni lati fi ẹmi imoore han sawọn olukọ”

Lakootan, asoju ajọ ADACI NIGERIA Deola Fate ki gbogbo awọn tiwọn fi aaye silẹ lati wa sibi idije naa ,o salaye pe, ajo naa ti setan lati maa gbaruku ti asa ati ise ilẹ adulawọ, bee ni wọn ti pinnu lati gbe e de ibi giga nitori naa eto idije naa yoo maa tesiwaju lai fọtape, toripe erongba ajo naa ni lati pe awọn ọ̀dọ́  wa sinu agbo asa ati ise. O tun wa  dupẹ lowo aare ajo naa lorile ede Nigeria Oloye Fakunle Oyesanya fun atileyin tiwọn n se fun ajo naa ni gbogbo igba.

 

Ademọla Adepọju

Leave A Reply

Your email address will not be published.